Oriki Asunmo

Oriki Asunmo

  • Asunmo nmoro nmope
  • Omo ibu Owo ti n je Asunmo
  • Omo ajagajigi Oogun
  • Igi gbogbo kiki Oogun
  • To ti Efon wa sowo l’oyo ile
  • Oni oyo dun Oun O rele mo
  • Omo ewe kewe, Omo egbo kegbo
  • O ja kinni O ja keji, O ja keta
  • Ibe lo di Omo Owa si
  • Asunmo Ore egba
  • Animashaun ore eniyan rere
  • Ijesa Omo Oloba loro
  • Nmoronmope
  • Omo alaaye, Omo ibu owo
  • Omo Olobi wowo tiwo
  • Omo bi o kemi ni kiki
  • Mi O fe mi gege, mio gbeyin
  • Dinlogun,
  • Omo yawo awo fi ba Obi
  • Asunmo Ogomoro iyekan Oba
  • Ma fi yaje e, Olorun ma fiyaje
  • Omo Animashaun
  • Ma fosi ta a, Olorun ma fosi ta
  • Omo Animashaun
  • Asunmo Ore Egba
  • Animashaun Ore Eniyan rere,
  • Sun un re o baba wa.
Home — Animashaun Family